Ìtàn Jésù ní Tòótọ́
Wo Ìtàn Jésù ní Tòótọ
Àwọn ìbẹ̀wò Sí Ojú-ìwé Náà
Àwọn ènìyàn Gbàdúrà
Bí o bá gba àdúrà ìgbàlà náà, o ti di ọmọ Ọlọ̀run.
“Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là.”
—Róòmù 10:9
O lè gbàdúrà pẹ̀lú wa nísìnyí fún ìgbàlà rẹ:
Ọlọ́run,
Mo jẹ́wọ́ wípé Jésù ni Olúwa. Mo gbàgbọ́ wípé a bí I láti ọwọ́ wúndíá, Ó kú lórí àgbélèbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, tí Ó sì jí kúrò nínú òkú ní ọjọ́ kẹta. Lónìí, mo jẹ́wọ́ wípé mo ti ṣẹ̀ sí Ọ, tí kò sì sí ohun tí mo lè ṣe láti gba ara mi là. Mo béèrè kí o dáríjì mí, tí mo sì fí ìgbékẹ̀lé mi sínú Jésù nìkan. Mo gbàgbọ́ wípé mo ti di ọmọ Rẹ̀ báyìí àti wípé n ó lo ayérayé mi pẹ̀lú Rẹ. Tọ́ mi l’ójoojúmọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí àti inú mi, kí ń sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí ara mi. O ṣeun fún gbígbà mí là nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, Ọmọkùnrin Rẹ. L’órúkọ Jésù ni mo gbàdúrà. Àmín.